Lọjó Kinni, Osù Kẹta (Ẹrẹnà) 2013, àwọn olùlo twitter tó gbọ Yoruba yóò sọọ láti àárọ dálẹ.

A bẹrẹ ètò yìí lódún tó kọjá láti fá Twitter lẹsẹ kí wọn ba le fi ọn ba le fi èdè Yorùbá sí ọkan lára àwọn èdè àgbáyé  tí a ti lè lo gbàgede náà. A se aseyọrí díẹ nígbà tí Twitter dá wa lóhùn padà láti ẹnu òsìsẹ ògbifọ wọn kan tí ó sọ wípé wọn ti gbọ ohùn wa, sùgbọn yó se díẹ kí wọn tó fi ọn tó fi Yorùbá kún-un nítorí àwọn ètò díẹ tí wọn ní láti se kí ó tó le seése.
imagesA tún ti bá wọn sọrọ lẹẹkan síi nígbà tí òsìsẹ Twitter miran @lenazun wá láti bèèrè irú èka Yorùbá tí a máa n lò láti se ògbifọ àti láti kọ ìwé ìjọba ní Yorùbá. (Ìdáhùn rẹ ni Yorùbá Àríwá-Ìwọ Oòrùn, tí a n sọ ní Òyó). Léyìn èyí, nkò gbọ ohun mìràn.

Jọ Sísọ Yorùbá Ní Twitter ní March 1, 2003* jẹ láti tẹsíwájú èyí tí a bẹrẹ lódún tó kọjá, sùgbọn nísìnyí láti fi ẹwà èdè abínibí wa hàn nínú ayé ẹrọ ayélujára tí a n gbé nísìnyí. Ó lè má sẹlẹ rárá wipe ọjọ kan yóò wà tí èdè tí gbogbo aráyé yóò máa sọ lórí ayélujárá yóò jẹ èdè abínibí nìkan, torípé àwọn tó n sọ wón kò pọ púpọ (Yoruba tíẹ sí ní ju ọgbọn million lọ), sùgbọn bí ọnà láti sọ èdè yìí bá ti se wà, bẹẹ náà ni a ó se ní àìmọye ojúlówó ọnà láti fi àsà àti ìse wa hàn fún gbogbo àgbáyé

Bí a se seé lésìí, àwọn hashtags láti lò lọdún yìí ni #tweetYoruba àti #twitterYoruba. Fún àwọn tí wón bá tún fẹ fa Twitter lẹsẹ wípé kí wọn jẹ kí á se ògbifọ gbàgede náà sí Yorùbá,  kí wón sèdà tweeti wọn sí @twitter àti @translator.

________

*February 21 ni Ọjọ Tí a Yà Sọtọ Lágbàáyé Fún Sísọ Nípa Èdè Abínibí

________

Èyí ni atọka ètò náà. Jọwọ fi han gbogbo àwọn ènìyàn rẹ lórí èrọ ayélujára

TweetYorub2013 (1)

________

speakafrica

Àwọn olùlo twitter tí ó bá kọ àwọn oun tó mọgbọn wá jùlọ ní ọjọ yìí yóò gba asọ “Mo Le Sọ Yorùbá” àti báàgì ìfàlọwọ láti ọwọ @SpeakAfricaApps tí ó n se ìgbọwọ ètò yìí, ati kirediti lati owo  Think Oyo (@ThinkOyo). Ètò yìí tún wá pẹlú àjọsepọ àwọn wọnyìí náà: Molara Wood, ònkọwé (@MolaraWood), Alakowe Yorùbá (@AlakoweYoruba), The Yoruba Cultural Insittute (@yorubaculture), àti Kevin “Kayode” Barry (@KayodeOyinbo).

_____________

Read page in English

Random Posts

Loading…

VN:F [1.9.22_1171]
Rating: 0.0/10 (0 votes cast)
VN:F [1.9.22_1171]
Rating: 0 (from 0 votes)